Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ekiti ti fi hàn pé àwọn múrasílẹ̀ de ètò ìdìbò Gbogbogbò, Ọdún 2023.

0 364

Ile-iṣẹ Ọlọpaa ni Ipinlẹ Ekiti ti fi imurasilẹ wọn fun Eto Idibo Gbogboogbo dun 2023 han pẹlu akitiyan lati fi alaafia mulẹ ni gbogbo awọn ibudo idibo kaakiri Ipinlẹ Ekiti. Eto idibo naa lọ ni irọwọ àti irọsẹ lai si gbọnmi-si-omi-o-to nibi kankan.

Agbẹnusọ ile-iṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu ni ilu Ado-Ekiti sọ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ awọn niwọn ti wa ni ibudo idibo wọn lati ri daju pe aabo to gbopọn wà fún awọn ondibo, ati awọn nnkan elo miiran to nii ṣe pẹlu eto idibo.

Ọga Ọlọpaa DSP Abutu ṣalaye pe awọn ti bẹrẹ  eto aabo to peye bayii lati igba ti eto idibo Gomina ti waye ni ipinlẹ Ekiti lọdun 2022.

O ni:

Ṣeranti pe ko pẹ ti a ṣe eto idibo Gomina ni ipinlẹ yii, eyi ti a ṣe laarin ọdun to kọja  a si ti bẹrẹ igbaradi to nipọn fun eto idibo gbogboogbo yii lati igba naa

Ninu ọrọ rẹ, Abutu fi mulẹ pe gbogbo awọn oṣiṣẹ awọn ni wọn ti gba idanilẹkọọ loriṣiriṣi fun eto idibo yii ki o to di asiko yii.

Igbakeji agbẹnusọ ile-iṣẹ Ọlọpaa ni Ipinlẹ EkitiỌga Ọlọpaa APS Ẹbunoluwa Okunọla fi kun ọrọ naa nigba to sọ pe Ajọ INEC gbe oṣugba kare fun ile-iṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ekiti ni asiko eto idibo Gomina to kọja, atipe ori eyi ni awọn gbe akitiyan awọn le fun aṣeyọri eto idibo Aarẹ ati ile igbimọ aṣofin apapọ to n lọ lọwọ yii ni Ipinlẹ Ekiti.

 

Olanrewaju Lagada

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button