Igbákejì Ààrẹ Yemi Osinbajo àti ìyàwó rẹẹ̀ Dolapo ti dìbò Ààrẹ tó ń wáyé káàkiri orílẹ̀-èdè lónìí.

Wọn dìbò ni ọjọ Sátidé ní ẹka Idibo kẹrinla, Egunrege, ní ìjọba ìbílẹ̀ Ikenne.

Àwọn oṣiṣẹ ijọba ti àjọ Idibo Orilẹ-ede Nàíjíríà (INEC) dé ibi ìdìbò ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní dédé aago méje ku ìṣẹ́jú mẹ́rìnlá ti ijẹrisi àwọn olùdìbò àti ìbò síì bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹjọ kọja isẹju marunlelọgbọn owurọ.

Ọláyinká Akíntọ́lá.
Leave a Reply