Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari tí bú ẹnu àtẹ́ lú ipaniyan burúkú tí wọ́n pá Oyibo Chukwu, ẹní tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ní Enugu East Senatorial District àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní Gúúsù Ìlà Oòrùn Nàìjíríà.
Ààrẹ náà gbàgbọ́ pé àwọn tó hùwa áìṣédéédé yìí, ní Awkunanaw, ní ìjọba ìbílẹ̀ Enugu South ní Ìpínlẹ̀ Enugu, kó ní ibọwọ fún ìgbésí ayé àti iyì ènìyàn, ní ìdí èyí wọ́n bèrè fún ìbínú ènìyàn àtí ìdájọ́ Ọlọrun.
Nínú ifiranṣẹ kàn, Ààrẹ ṣé ìdánilójú rẹ̀ lórí ìdìbò tí kò ní iwa-ipa àti aibikita.
Tún kà nípa: Ìdìbò Gbogbogbò 2023: Ààrẹ Buhari Bálẹ̀ Sí Ìpínlẹ̀ Katsina
Ó rán gbogbo àwọn olòṣèlú létí pé àyànfẹ́ àwọn olùdìbò ló ṣe pàtàkì, nítorí náà gbogbo ọmọ Nàìjíríà tó bá ṣé tán látí dìbo láì sí ìbẹrù kánkan.
Ààrẹ pàṣẹ fún àwọn àjọ élétó ààbò látí wa àwọn tó húwà burúkú yìí, kódà bó tí n bá àwọn ìdílé, ẹgbẹ́ àgbàjọrò (NBA) àtí ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party kẹ́dun.
Ó gbàdúrà fún ìsinmi ọkàn olóògbé náà àti ìtùnú fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀.
Lekan Orenuga
[…] Tún kà nípa:Ààrẹ Buhari Bú Ẹnu Àtẹ́ Lú Ìpànìyàn Ọmọ Ẹgbẹ́ Òṣèlú Labour Party […]