Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé-ẹ̀kọ́ Gíga Àwọn Ọmọ-ogún Nàìjíríà Tí Kọ́ Àwọn Ọjẹ̀-wẹ́wẹ́ Ilé-ẹ̀kọ́ Náà Ní Ìjà Ojú Omí

0 225

Ilé-ẹ̀kọ́ gíga àwọn ọmọ-ògún Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (NDA), tí ṣètò ìkẹ́kọ̀ lórí omí fún ọgọrùn lé ní ọgọrin àwọn ọmọ ilé-ìwé náà ní ìpínlẹ̀ Kaduna.

Alákóso NDA, Major General Ibrahim Yusuf sọ́ èyí dì mímọ̀ làkókò tó ń bá àwọn akọroyin sọrọ ní Ilẹ̀-òfurufú Nàìjíríà, Nigeria Air Force Base Dam ní Kaduna pé, eléyìí ní àkọ́kọ́ irú rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bó tí sọ, àwọn ọmọ ilé-ìwé ọgọ́rùn-ún lé ní ọgọrin 180 tó kópa nínú ìdíje náà ní á ṣé akojọpọ wọ́n látí oríṣiríṣi àwọn battalions bí Mogadishu, Dalet, Abyssinia àtí Burma tí wọ́n yóò sì kópa nínú ìdíje mẹ́rin bíí ifi bàtà sáré, ifi bàtà sáré òní gbági-gbági, gbígbé àwọn àrà wọ́n tó f’arapa àtí bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ́.

Ó ṣàlàyé pé tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ọjọ́ kàn tàbí méjì ní ìdíje náà fi máa ń wáyé ní Jos, olú-ìlú Plateau. Ṣùgbọ́n ní báyìí, á tí fí kùn ètò ìlànà ikẹkọ ilé ẹ̀kọ́ náà.

Tún kà nípa: Ìgbìyànjú Ń lọ Lọ́wọ́ Látí Gbá Òṣìṣẹ́ Ilé Iṣẹ̀ Ọmọ Ogún Obínrin Tí Wọ́n Jigbe Sílẹ̀ – Ọmọ Ogún Nàìjíríà

O gbóríyìn fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà fún akitiyan wọ́n, ó ṣé àkíyèsí pé Battalion Mogadishu gbìyànjú púpọ nínú gbogbo ìdíje tí wọ́n tí díje.

Àwọn ọmọ ogún Mogadishu ló gbégbá olubori pẹ̀lú ojú-àmí ọ̀ọ́dúrún lé logójì 340, Dalet wá ní ipò Kejì pẹ̀lú ojú-àmí ọ̀ọ́dúrún lé lógún 320, nígbà tí Burma wá ní ipò kẹta pẹ̀lú ojú-àmí ìgbá lé ní ọgọrin 280 tí Abyssinia sí wà ní ipò kẹ́rin pẹ̀lú ojú-àmí ọgọrùn lé lọgọrin 180.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button