Ààrẹ Muhammadu Buhari ní ọjọ́ Àìkú fí ifiránṣẹ́ kàn ránṣẹ́ sí ilé látí Addis Ababa, Olú-ìlú Ethiopia, níbí tó wà nínú àpéjọ Africa Union AU Summit, ó sọ pé òún mọ́ ìnira tí àwọn aráàlú ń kojú nípa ètò ìjọba lórí owó, “eyi tí yóò mú ìlọsíwájú bá Orílẹ̀-èdè náà lápápọ̀” tí fà. Ó sí ń bẹ̀bẹ̀ fún sùúrù síi bí ìjọba ṣé ń gbèrò láti mú ayé dẹ́rùn fún àwọn aráàlú.
Ààrẹ náà dúpẹ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà fún bí wọ́n ṣé yan an láti di Ààrẹ fún sáà méjì, o sí rọ́ wọ́n látí dìbo fún Asíwájú Bola Ahmed Tinubu lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ APC nítorí pé “O ṣee gbẹkẹle àti pé mó mọ̀ pé yóò gúnlè àṣeyọrí wà.”
Tún kà nípa: Ìbò Ọdún 2023: Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC Se Ìfilọ́lẹ̀ Ìwé Ọgbọ́n Àtinúdá
Nínú ifiranṣẹ ìpolongo sí àwọn olúdìbò, Ààrẹ ní pàtó tí pé “Àwọn alákóso ìbílẹ̀, àwọn olórí ẹsìn àtí àwọn òbí látí kìlọ fún àwọn ọmọ wọ́n àti àwọn alatilẹyin wọ́n látí má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ló wọ́n látí dá wàhálà sílẹ̀.
Ààrẹ náà tẹnu mọ́ ọn pé olùdíje ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti ṣe àfihàn ìfẹ́ rẹ̀ fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè àti àlàáfíà àwọn ènìyàn rẹ̀, nìdí èyí “Ẹ́ dìbo fún”
Lekan Orenuga
Leave a Reply