Igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Osibajo ti sọ ilé ìwòsàn tí ó gbà tó bẹ́ẹ̀dì ọgọ́rùn-ún fún ìtọ́jú àwọn Obìnrin àti Ọmọdé di lílò ní ìlú Ipẹru-Rẹmọ, Ìpínlẹ̀ Ogun
Igbákejì Àar̀ẹ se àpèjúwe iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bíi aseyọrí fún ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari. Ìdásílẹ̀ ilé ìwòsàn náà jẹ́ ìsàfihàn ìfarajì ìjọba àpapọ̀ láti pèsè ilé ìwòsàn tí ó dára fún ìtọ́jú àwọn obìnrin àti ọmọdé ní àgbègbè náà.
Àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Ogun dúpẹ́ fún àseyọrí iṣẹ́ náà, àtipé yóò mú ìrọ̀rùn bá ìtọ́jú àwọn obìnrin àti ọmọdé ní àgbègbè náà.
Leave a Reply