Olùkópa nínú eré kan tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Tùmínínú Olúyọ̀lé ti gbégbá orókè tí wọ́n sì gbé òsùbà fún-un níbi ayẹyẹ fífi nǹkan ìsẹ̀mbáyé hàn, léyìí tí ó tún fún àwọn olùkọ eré ní ànfààní láti wòye sí àwọn iṣẹ́ẹ wọn.
Eré náà sọ̀rọ̀ nípa àìgbọ́ra-ẹni-yé láàrin àwọn arìnrìnàjò aláwọ̀ dúdú àti àwọn ènìyàn dúdú ilẹ̀ Amẹrika. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn eré tí wọ́n se àsàyàn rẹ̀ níbi ayẹyẹ náà.
Ó tún sọ ànfààní tí ó yẹ kí ènìyàn aláwọ̀ dúdú máa ní, ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà gẹ́gẹ́ bíi olùgbé, ó sì fi ẹ̀kọ́ nípa gbígbé lálàáfíà ọmọnìyàn léde.
Leave a Reply