Ààrẹ Orílẹ̀-èdè South Africa, Cyril Ramaphosa ti Kéde ìfiṣé sílẹ̀ igbákejì rẹ̀, ọ̀gbẹ́ni David Mabuza, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àtìlẹ́yìn tó gbúpọn tí ó fún láti ọdún máàrún ùn sẹ́yìn.
Ìròyìn rò pé kò ya ààrẹ lẹ́nu nítorí pé ó ti sọ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò ju awà sílẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yí.
Síbẹ̀síbẹ̀ yóò wà ní ipò títí ààrẹ yóò fi kéde ẹlòmíràn tí wọ́n gbàgbọ́ pé yóò jẹ́ igbákejì ààrẹ ọmọ ẹgbẹ́ ANC, ọ̀gbẹ́ni Paul Mashatile.
Orílẹ̀-èdè South Africa yóò ṣe àtúntò sí àwọn orísìí ipò ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ní kété tí wọn bá ti kéde ètò ìṣúná wọn ọlọ́dọọdún.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply