Take a fresh look at your lifestyle.

Ènìyàn Pàtàkì, Ọmọ Bíbí Ìpínlẹ̀ Bauchi Yóò Jẹ Anfààní Ìlera Ọ̀fẹ

0 398

 

Àjọ Bauchi State Health Contributory Management Agency, BASHCMA, sọ pé àwọn tí kọ orúkọ àwọn ènìyàn pàtàkì, ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Bauchi ti yóò jẹ ànfààní Ìlera ọ̀fẹ́ sílẹ̀.

 

Àwọn tí yóò jẹ ànfààní yi ní wọ́n sà kà kiri ìjọba ìbílẹ̀ ogún ti ìpínlẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí Alága àjọ náà, Dókítà Mansur Dada se sọ .

Bí ó se sọ, ètò Ìlera náà yóò jẹ ti ipele àkọ́kọ́ àti ti ipele gíga tí Ìlera tí ó péye fún mùtú mùwà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.

 

Síbẹ̀síbẹ̀, Olùdarí àjọ National Senior Citizens Centre, NSCC, Mustapha Yakubu sọ wí pé pínpín àpò ẹ̀fọn ìdáàbòbò fún àwọn àgbà yóò bẹrẹ láìpẹ́.
.
Ògbéni Yakubu sọ pé ogún ẹgbẹ̀rún owó ìfifúnni ni wọ́n o ṣètò fún àwọn ènìyàn pàtàkì, ọ̀mọ bíbí Ìpínlẹ̀ náà.

Ó so pé, “Wọ́n ti fi ètò náà lọ́lẹ̀ ní ọdún 2022”.

Ní ti ètò ìrónilágbára, àjọ National Directorate of Employment, NDE ti kọ́ àwọn àgbàgbà méje nípa ìgbèrú ètò ìdásẹ́-sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà.

 

Adarí àjọ NDE ní ìpínlẹ̀ Jigawa, Mr Miwa Lasco sọ pé àwọn ọkùnrin márùn ùn àti Obìnrin méjì ló jẹ ànfààní yìí ni ètò kíkọ́ wọn bí ati ń hun nǹkan, iṣẹ́ gbénàgbénà, iṣẹ́ awọ, alágbẹ̀de, ìkòkò amọ̀ àti apẹ̀ẹ̀rẹ híhun.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button