Ilé Ẹjọ́ àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fi ìdájọ́ léde ní Ọjọ́rú (Wednesday) tí ó sí pásẹ fún ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ láti gbésẹ̀ kúrò lóríi gbèdéke kíkó owó Náírà tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí kúrò nílẹ̀ nínú osù kejì.
Àwọn Adájọ́ méje, eléyìí tí Adájọ́ John Okoro darí wọn ni ó dájọ́ náà, èyí tí ìpínlẹ̀ mẹ́ta ní àgbègbè àréwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Kaduna, Kogi àti zamfara pè. Ó sì sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ kẹẹ̀dógún osù kejì ọdún 2023 fún ìtẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ náà.
Agbẹjọ́rò àgbà tí ó ń sojú àwọn olùpẹ̀jọ́ Ọ̀gbẹ́ni A.I. Mustapha (SAN) rọ Ilé Ẹjọ́ Àpapọ̀ láti bojú àánú wo ìpèpè rẹ̀ fún ìsọ̀kan, àlàáfíà àti ìfi àdájọ́ òdodo rinlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Àtipé kí ìsẹ̀lẹ̀ náà má baà fa wàhálà, nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé ìfowópamọ́ ni ó ti wà ní títì pa látàrí rògbòdìyàn àìrí owó ná fún àwọn ará ìlú.
Leave a Reply