Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, Sẹ́natọ̀, Ahmad Lawan sọ pé ìdájọ́ ọjọ́ ajé ní ilè ẹjọ gíga ilẹ̀ wa lórí awuuyewuye ẹni tí yóò gba tíkẹ̀tì lọ sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin láti Ìpínlẹ̀ Yobe fún ẹgbẹ́ APC jẹ́ ìdájọ́ rere, ó tún jẹ́ orire fún ẹgbẹ́ APC àti fún ìjọba tiwantiwa.
Ilé ẹjọ́ gíga nínú ìdájọ́ rẹ̀ fi múlẹ pé Sẹ́netọ̀ Ahmad Lawan ló jáwé olúborí nínú ìbò ẹni tí yóò sojú fún ìpínlẹ̀ Yobe gẹ́gẹ́ bí Sẹ́nétọ̀ nínú ìbò tí yóò wáyé ní ọjọ́ karùn ún dín lọ́gbọ̀n oṣù yí.
Ìdájọ́ náà fagilé ẹnití ilé ẹjọ́ kékeré ti sọ pé ó yege tẹ́lẹ̀ rí, ọ̀gbẹ́ni Bashir Machina gẹ́gẹ́ bí olúborí.
Nígbàtí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, Sẹ́netọ̀ Lawan sọ wí pé “ìdájọ́ òdodo ni ìdájọ́ náà, oríire sì ni fún ẹgbẹ́ APC ní Ìpínlẹ̀ Yobe àti fún gbogbo ẹgbẹ́ APC káàkiri Nàìjíríà.
Ìjọba tiwantiwa ló wà lójú ìse. Ilé ẹjọ́ kékeré se ìdájọ́ wọn, ilé ẹjọ́ gíga ilẹ̀ wa wá parí rẹ̀ pẹ̀lú ìdájọ́ tiwon tó dára, mo gbóríyìn fún wọn fún ìdájọ́ ododo, eléyìí á ró ìjọba tiwan tiwa lágbára.
Mo sì tún fi eléyìí dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹgbẹ́ All Progressives Congress (APC) nípa gbígbé ẹjọ́ náà lọ sí kóòtù, nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ń kò fẹ́ gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn afẹ́ni fẹ́ ire mi.”
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply