Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Anambra Fọ́wọ́ Sọya Láti Dẹkùn ọ̀wọn Gógò Epo Ní Ìpínlẹ̀ Náà.

0 281

Ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra tí kéde àrídájú rẹ̀ láti dẹkùn ọ̀wọ́n gógò epo láàárín àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ náà.

Kọmísọ́nà fún epo ròbì ati ohun àlùmònì ni ìpínlẹ̀ náà , Agbẹjọ́rò Anthony Ifeanyi sọ èyí di mímọ̀ nínú ìpàdé pẹ̀lú àwọn òntàajà epo ròbì èyí tó wáyé ni ọfisi re ni Awka Olu ìpínlẹ̀ náà.

Agbẹjọ́rò Ifeanyi pe àkíyèsí wí pé àwọn ilé èpo míràn n di mìtà ti wọ́n n fi ta epo kún, èyí kò sí bá oju mu rara, ó wá rọ wọn láti ti ọwọ́ ọmọ wọn bọ asọ fun àǹfààní awọn ará ìlú.

 

Ó tẹnumọ wí pé ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra yóò ṣe gbogbo ohun to wà ní ìkápá rẹ láti rí dájú pé epo ròbì dì tita láyìí gbóbówólóri.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button