Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Yóò Tún Ìpàdé Ṣe Ti Ilé Ìfowòpamọ́ Àpapọ Ba Kùnà Lati Wa Ojútùú Sí Rògbòdìyàn Owó Tuntun Àti Owó Àtijọ Orílẹ-èdè Nàìjíríà.

0 179

Agbẹnusọ fún ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Fẹmi Gbajabiamila tí sọ wí pé ilé ìgbìmọ̀ yóò tún ìjókò jó kó tó di ọjọ́ ìdìbò ti yóò wáyé ni ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù Kejì ọdún yìí,bi ilé ìfowópamọ́ àpapọ orìlẹ́-èdè Nàìjíríà bá kùnà láti mu  iyànjú ba ọ̀rọ̀ tó ńlo lọ́wọ́ nípa pàsípàrò owó tuntun àti owó atijọ.

Adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin sọ wí pé àwọn yóò tèsíwájú látí ma mójútó bi ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀, bi ọ̀rọ̀ owó náà ṣe ńlo sí, àti láti bá Gómìnà bánkì àpapọ̀ ṣe ìpàdé lórí ọ̀rọ̀ naa

Ẹnu adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní Surulere ni ìpínlẹ̀ Eko ni ọ̀rọ̀ náà ti wáyé nínú ìpàdé ara ìlú tó wáyé ní ọjọ́ ìsinmi. O ní ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí fi kún ọjọ́ diẹ láti mú ìyípadà bá ìṣòro ọ̀rọ̀ owó to ńlo lọ́wọ́lọ́wọ́

O wa gbàdúrà fún ìyípadà ọtun,ati ifọkanbalẹ wípé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ko ni dákẹ́ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button