Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ Alámòjútóó Ìsẹ̀lẹ̀ Pàjáwìrì Dóòlà Ẹ̀mí Àwọn Ènìyàn Níbi Ilé Tí Ó Dà Wó Lulẹ̀ Ní Ìlú Abuja

0 214

Kò dín ní ènìyàn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tí àjọ tí ó ń mójú tó ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì àti àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn dóòlà ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá Ilé tí ó dàwó lulẹ̀ ní Gwarimpa, Ìlú Abuja, olú Ìlú Nàìjíríà.

 

Ilé náà, eléyìí tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ni ó dà wó lulẹ̀ ní déédé agogo mọ́kànlá òwúrọ̀ Ọjọ́bọ̀ (Thursday) tí ó sì se ìpalára fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Títí òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì (Friday) àwọn àjọ tí ọ̀rọ̀ kàn náà ti dóòlà ẹ̀mí ènìyàn mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tí ènìyàn mẹ́ta míràn sì fi ara pa yánna-yànna.

 

Mínísítà olú Ìlú Abuja, ẹni tí ó se àbẹ̀wò sí àyè náà sàlàyé pé, ìsẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kẹta irú rẹ̀ ní àgbègbè náà, àtipé ìjọba ti setán láti wá ojútùú sí ìsòro náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button