Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà Ìlú Abuja Sọ Ayé Di Gbẹdẹmukẹ Látàrí Pípèsè Ilẹ̀ Ọlọ́ràá Fún Ètò Ọ̀gbìn

0 149

 

Mínísítà olú Ìlu Nàìjíríà Malam Muhammed Musa Bello ti jẹ́jẹ̀ẹ́ ìbásepọ̀ tí ó múná dóko pẹ̀lú àjọ tí ó ń se àmójútò ilẹ̀ fún ìpèsè ohun ọ̀gbìn tí ó dára.

 

Mínísítà, ẹni tí akọ̀wé àgbà ẹka náà, Ọ̀gbẹ́ni Adesọla Olusade sojú fún sọ pé ètò náà jẹ ìjọba lógún nítorí pé ilẹ̀ ọlọ́ràá tí yóò mú irúgbìn àti èso gidi jádè.

 

Ó wá fi àrídájú hàn pé, ìjọba yóò tẹ́wọ́ gba ẹnikẹ́ni láàyè fún ìrànlọ́wọ́ lójúnà àti mú ẹwà bá ilẹ̀ àgbègbè náà fún ètò ọ̀gbìn tí ó dára àti fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé Orílẹ̀-ede.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button