Gómìnà Ìpinle Ebonyi, Engr. David Umahi ti Gbósùbà ràbàndẹ̀ fún àjọ àgùnbánirọ̀,(NYSC) fún akitiyan wọn láti ri pé ìṣọ̀kan àti ìdàgbàsókè wà ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Umahi se èyí níbi ìgbaniwọlé ọmọ ẹgbẹ́ àgùnbánirọ̀ tí ìpín A ní àgọ wọn ní àríwá
Afikpo ìjọba ìbílẹ̀ ti ìpínlẹ̀ náà.
Alága tó gbenusọ fún Gómìnà, Ọ̀gbẹ́ni Charles Akpuenika sọ wí pé àwọn àgùnbánirọ̀ ti se bẹbẹ nípa mímú kí Orílẹ̀-èdè gbèrú sí àti kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan.
Àwọn àgùnbánirọ̀ náà se ìlérí láti máa tẹ̀síwáajú nínú ìwà ọmolúwàbí àti àlàáfíà wọn gẹ́gẹ́ bí Olùdarí won ní Ìpínlẹ̀ náà ti lù wọ́n ní ọ̀go ẹnu ṣáájú.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
[…] Tún kà nípa: Gómìnà Umahi Gbósùbà Ràbàndẹ̀ Fún Àjọ NYSC Fún Mímú Ìdàgbàsókè Bá Orílẹ̀… […]