Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ PDP Kọ Ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun

0 237

 

Ẹgbẹ́ PDP ti kọ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó fagilé Ọ̀gbẹ́ni Ademola Adeleke gẹ́gẹ́ bí Gómìnà tí wọ́n dìbò yàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun

Ẹgbẹ́ PDP sọ wí pé àwọn ọmọ Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun ló dìbò fún ẹgbẹ́ PDP tí wọ́n sì fi ìbò wọn gbé Ọ̀gbẹ́ni Ademola Adeleke wọlé ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù keje ọdún 2022

Nínú àkọsílẹ̀ tí alukoro àpapọ̀, ọ̀gbẹ́ni Debo Ologunagba sọ wí pé ” ìdájọ ilé ẹjọ́ náà yàtọ̀ sí èrò ọkàn àwọn ará ìlú tí wọn fi ìbò wọn gbé Olùdíje náà wọlé gẹ́gẹ́ bí
Gómìnà wọn.”

Ògbéni Atiku náà sọ ní tirẹ̀ pé,
ìgbésẹ tí ẹgbẹ́ gbé báyìí jẹ ìgbésẹ̀ láti yọ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ osun kúrò nínú àjàgà. Ní òpin gbogbo rẹ̀, wọn óò ṣẹ́gun. Kí gbogbo ọmọ Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lọ ní ìgbàgbọ́ nínú Gómìnà tí wọ́n fi ìbò wọn yàn. Ìmọ́lẹ̀ tó tàn ní Ọ̀ṣun kò ní kú.”

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button