Kọmisọna ọlọ́pàá tí Ìpínlẹ̀ Anambra ní South-East Nigeria, Echeng Echeng, ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ní Alex Ekwueme Square, Awka, Olú-ìlú ìpínlẹ̀ náà, darapọ̀ mọ́ àwọn Alákóso iṣẹ́ mìíràn ní ìpínlẹ̀, látí bú ọlá fún àwọn ológun àti àwọn òṣìṣẹ́ tó fi ẹ̀mí wọ́n lélẹ̀ fún ìsọkan orílẹ̀-èdè yìí.


Kọmisọna ọlọ́pàá náà sọ pé ìsàmì ọjọ́ náà fún wà ní ìdí látí ronú àtí láti rán wa létí àwọn ìrúbọ tí àwọn ẹgbẹ́ élétó ààbò wà ṣe lórí ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè yìí àti dídáàbò bò ẹ̀mí àti òun ìní.”
Akọroyin Voice of Nigeria jabọ pé àwọn òun pàtàkì tí ó wáyé náà ní àyẹwò tí àwọn ọmọ ogún Nàìjíríà, ọmọ ogún ojú omi, àtí àwọn ọmọ ogun Legion tí Gómìnà Ìpínlẹ̀ Anambra, Chukwuma Soludo, ádùrá àtí idakẹ jẹjẹ fún àwọn ológun tó ṣubu, fífi àwọn òun ọ̀ṣọ́ lélẹ̀ àtí àwọn òún ìsàmì pàtàkì mìíràn.
Lekan Orenuga
Leave a Reply