Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Ethiopia Múra Sí Wíwá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Tó Sálọ Látàrí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Tó Di Fífọ́

0 267

Àwọn elétò ààbò ní Gúsù ti orílẹ̀-èdè Ethiopia ti múra sí wiwí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó nù. Ìròyìn ròó pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹlẹ́wọ̀n ni abúlé Bule Hora, ní ibusọ̀ bàtà bi àdọ̀ta lé ní Irinwó sí Addis Ababa, ni ó sálọ léyìn ìkọ̀lù àwọn ènìyàn adihamọ́ra ogun.

“Àwọn ológun ìjọba ń wá wọn kiri,” Olórí ìlú náà ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ọgbà ẹ̀wọ̀n náà jẹ́ ilé àwọn ọ̀daràn pọ́nbélé ti àwọn ọmọ ogún ọlọ̀tẹ̀ sí jẹ́ ara wọn tí wọ́n tì mọ́lé lẹ́yìn tí àwọn ológun sígun.

Ìkọ̀lù tí ó wáyé láàrọ́ọ̀ kùtù ọjọ́ Àìkú jẹ́kí ènìyàn kan ku, èsọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n márùn ún bákannáà dá gbére fáyé, àwọn aláṣẹ sọ bẹ́ẹ̀.

“Gbogbo wọn ti sálọ. Wọ́n ju okòódínlẹ́dẹ́gbẹ̀ta tó ti sálọ, “ Olórí kan sọ bẹ́ẹ̀.

Wọ́n ti di ẹ̀bi ìkọ̀lù náà rú àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ ‘Oromo Liberation’, sùgbón àwọn ọmọ ogun náà kò fèsì.

Ní ìgbà àtijọ́, ikọ̀ ológun ti sọ pé àwọn ló tú àwọn olóṣèlú ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀ nínú àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní agbègbè Oromia tí se ìlú ààrẹ ilẹ̀ Ethiopia, Abiy Ahmed.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button