Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ INEC Bẹ̀rẹ̀ Àyẹ̀wò Àwọn Òṣìṣẹ́ Rẹ̀ Ní Ìpínlẹ̀ Niger

0 235

 

Àjọ Independent National Electoral Commission (INEC), ní Ìpínlẹ̀ Niger ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò àti se ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ènìyàn látàrí ìbò gbogbo-gbòò ọdún 2023.

Bí adarí àti olùkọ́ni ní ẹ̀kọ́ nípa ètò ìdìbò, Ògbẹ́ni Arthur Adzape se sọ, ètò àyẹ̀wò yóò wáyé lẹ́ka gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ ètò ìdìbò ti INEC ní ọjọ́ kẹtàadínlógún oṣù kínní, yóò sì parí ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù yìí, ọdún 2023.

Ó sọ pé àwọn tí wọ́n fẹ́ se àyẹ̀wò wọn ni àwọn tí wọ́n forúko sílẹ̀ fún àwọn ipò wọ̀nyí:
Presiding Officers (POs), Assistant Presiding Officers (APOs) àti Registration Area Council Managers (RACs).

Wọ́n sì sọ fún wọn pé kí wọ́n wá pẹlu: Ìwé erí wọn, káàdì pélébé ìdánimọ̀, àti káàdì pélébé ìdánimọ̀ tí wọ́n fi forúkọsílẹ̀ tí wọ́n fi gbà wọ́n láti orí ẹ̀rọ ayélujára.

Ọjọ́ tí wọn yóò ṣe àyẹ̀wò ti ipò “Supervisory Presiding Officers” (SPOs) ni wọn yóò kéde rẹ̀ láìpẹ́ láti ọ̀dọ̀ àjọ
INEC.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button