Sénétọ̀ tó ń ṣiṣẹ́ sìn ìpínlẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ti gúsù Ìpínlẹ̀ Nasarawa, Sen. Umaru Al-Makura ti fi ọpẹ́ rẹ̀ hàn sí ààrẹ Muhammadu Buhari fún Ìbuwọ́lù ìwé ìdásílẹ̀ ifáfitì àpapọ̀ ti ilé-ìwòsàn ìkọ́ni- lẹ̀kö tó kalẹ sí Lafia.
Sénétọ̀ náà tó tún jẹ́ Gómìnà àná tẹ́lẹ̀ ipinlẹ̀ náà fi ìgbóríyìn náà hàn nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ Àìkú ni ìlú Lafia.
Bí sénétọ̀ náà se sọ, ” inú mi dùn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ ló kún inú mi, ní agbára Ọlọ́run, oun tí mo lóyún rẹ̀ sínú nígbàtí mo jẹ́ Gómìnà ló wá sí ìmúṣẹ yìí.”
Ó sọ wípé ilé-ìwòsàn náà yóò wúlò fún Ìpínlẹ̀ náà nipa kikọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ Oníṣègùn òyìnbó, yóò sì tún wúlò fún ìlera àwọn ènìyàn.
Ìbuwọ́lù Ìwé ìdásílẹ̀ Ilé Ìwòsàn ẹ̀kọ́ni ti Lafia wà lára ìwé ìsọdòfin tí ààrẹ bu ọwọ́ lù ní àìpẹ́ yìí.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply