Olùdíje ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Atiku Abubakar, ti fi ìpóruru ọkàn rẹ̀ hàn látàrí ìkọlù ọkọ̀ Reluwé ní etikọ̀ ọkọ̀ ojú irin tó wáyé láìipẹ́ yìí ní agbègbè Igueben, ìpínlẹ̀ Edo tí wọ́n sì jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn gbé sálọ láti ọwọ́ àwọn afunrasí darandaran.
Atiku, nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ àìkú jẹ́ kó di mímọ̀ pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù náà buru jáì lára ìtàn àilabo búburú tó wáyé ní orílẹ̀-èdè yii.
Nígbàtí oǹdíje ipò ààrẹ náà ńkẹ̀dùn pẹ̀lú àwọn tó lùgbàdí ìkọlù àti ìdílé wọn, ó sọ wípé ” Ọkàn òun àti ìdílé òun wà pẹ̀lú àwọn tó lùgbàdì ìkọ̀lù àti ìdílé wọn nínú gbígbà àdúrà fún wọn kí wọn leè padà dé láàyè àti ní àlàáfíà.”
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply