Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ̀rún Lọ́nà Ìgbá Ènìyàn Ló Wà Níbí Ìsìnkú Pope Benedict XVI

0 286

O fẹ́rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìgbá (200,000) ènìyàn ló bú ọlá fún Pope Benedict XVI làkókò ìsìnkú rẹ̀ lẹ́yìn ayẹyẹ ọjọ́ kẹta ní Vatican City.

Pope Francis ní yóò ṣé àkóso ìsìnkú. Ìgbà àkọ́kọ́ níyì ní ogún-lè-ní-gbà ọdún tí Pope tó wà lórí aleefa yóò dárí ìsìnkú tí aṣáájú rẹ̀, Vatican sọ.

Pope àtijọ náà kù ní pọ́pọ́ ṣèṣẹ̀ Ọdún Tuntun ní ẹní ọdún Márún ùn-dín-lọgọrùn (95), nípasẹ̀ àìlera àrà rẹ̀.

Ẹgbẹẹgbẹrun ènìyàn ní a n’ireti látí wá níbí ìsìnkú náà ní Square St Peter, ní iwájú St Peter’s Bisilica.

” Nítorípé Benedict kìí ṣé olórí ìlú mọ́ nígbà tí o kú, àwọn aṣojú látí Ìlú Italy àti Ìlú àbínibí rẹ̀ “Germany” nìkàn ní yóò wà níbẹ. Àwọn Olùdarí mìíràn tí yóò wà níbẹ láì gbà àṣẹ ní Ọba Philippe tí Belgium àtí Ọba Obirin Letizia tí Spain, àwọn Olùdarí Poland àtí Hungary.” Ilé iṣẹ́ Ìròyìn Catholic

Orílẹ̀-èdè Germany yóò lú agogo ìjọsìn ní àgó Mọkanla (10:00GMT) gẹ́gẹ́ bí ààmì ìrántí Olóògbé náà. Ẹ̀wẹ̀, Orílẹ̀-èdè Portugal yóò kéde ọjọ́ ọfò tirẹ̀, nígbà tí Orílẹ̀-èdè Italy yóò tá àsìá àwọn ilé ìṣẹ́ nlá nlá sí ìdajì jakejado Orílẹ̀-èdè náà.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button