Take a fresh look at your lifestyle.

U23 AFCON : Junior Syli Stars Yóò Pàgọ́ Fún Ọ̀sẹ̀ Méjì

0 336

Ní́ ìmúrasílẹ̀ fún ìdíje bọ́ọ̀lu AFCON tí ọjọ́ ori wọn kò lé ní mẹ́tàlélógún lọ (U23 African Cup of Nations ) ti ìpele ìperegedé, àjọ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Guinea(Guinea Football Federation) ti ṣètò igbaradi olósẹ̀ méjì fún àwọn agbábọ́ọ̀lù wọn, Junior Syli stars.

Agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Guinea yóò koju ti Naijiria,Olympic Eagles ni ipele àsekágbá ìperegedé lẹ́yìn ìgbà tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Junior Cranes ti ilẹ̀ Uganda ti kéde pé àwọn kò ní ìfẹ àti kópa mọ́

Orílẹ̀ èdè Naijiria ti dé ipele tó kẹ́yìn nígbà tí wọ́n lù Orílẹ̀-èdè Tanzania bíi ẹni lù aṣọ òfị̀ ní ayò mẹ́ta sị́ oókan ní àpapọ̀.

Olúborí láàrín Naijiria àti Guinea ni yóò lọ sojú ìdíje náà tí orílẹ̀-èdè Morocco yóò gbàlejò rẹ̀ ní ọdún 2023.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button