Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdíje Elẹ́yin Lórí Tábìlì: Adégòkè Borí Nínú Ìdíje Tí A Fi Sọrí Thomas-Ọkọ́ya

0 229

 

Agbábọ́ọ̀lù ẹlẹ́yin lórí tábìlì, Muiz Adégòkè ti já ewé Olúbori ní ìdíje ẹlẹ́kẹrìnléláàdọ́ọ̀ta ti Mọladé Ọkọ́ya-Thomas Table Tennis Championships tó wáyé nínú gbọ̀ngan
Molade Okoya Thomas ní pápá Teslim, ìlú Eko.

 

Adégòkè lu Olúborí àtijọ́, David Fayele ní àmì ayò: 4-2 (11-7, 15-13, 11-6, 8-11, 6-11, 11-6) gẹgiẹ bí Olúborí tuntun.

 

Ní ipele tó kángu sí àsekágbá, Adégòkè ti kọ́kọ́ lu Àkànbí ní ayò mẹ́rin sí méjì kó tó peregedé sí ipele àsekágbá.

 

Odúsànyà ní tirẹ̀ náà lu Ànú Anjùwọ́n bí ẹni lu aṣọ òfì ní ayò mẹ́rin sí òdo, 4-0 (11-5, 11-5, 11-5, 11-6).

 

Àseyege Bọ́sẹ̀ Odúsànyà yìí kò lẹ́gbẹ́ nítorí ó jẹ́ àseyege ẹlẹ́kẹjọ rẹ̀ ní ti ìdíje ẹlẹ́nikan (women’s singles) ti àwọn obìnrin.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
.

Leave A Reply

Your email address will not be published.