Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Ṣí Afárá Niger Kejì Fún Àkókò Kérésìmesì

0 245

Afárá Niger Kejì ní wọ́n tí kéde ṣiṣi rẹ̀ sílẹ̀ fún oṣù kàn ní àkókò Kérésìmesì àtí ọdún tuntun.

Mínísítà fún iṣẹ́ agbaṣe àtí ilé ilé kíkọ́ ní Nàìjíríà, Ọgbẹni Babatunde Fashola, pàṣẹ ṣiṣi afárá náà láti àgó méjìlá òru ọjọ́ kẹrinla, Oṣù Kejìlá ọdún 2022 sí ọjọ́ karundinlogun Oṣu Kini, ọdun 2023 nígbàtí o ṣé àyẹ̀wò afárá náà fún rírìn ọkọ.

Mínísítà náà tọkasi pé ìdí tí Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣé ní kí wọ́n parí afárá náà ní látí ṣé idínkù òṣì tó ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ sunkẹrẹ-fakẹrẹ ní ọpọlọpọ wákàtí tó ń wáyé lórí afárá Niger àkọkọ́ nígbà Kérésìmesì.

O sọ pé kí àwọn awakọ̀ dẹkùn ìwà aibikita lóri afárá náà nitori aburú ìjàmbá ọkọ.

“Àbájáde sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ jẹ́ òun tí a ri ní báyìí gẹ́gẹ́ bí òṣì tí kìí ṣé nípasẹ owó, ṣùgbón lílò ọjọ́ méjì sí mẹ́ta níbí ìgbìyànjú látí sọdá afárá yìí jẹ́ òṣì. Ìgbésẹ yìí jẹ́ òun idẹrun fún àwọn ènìyàn látí kọjá lórí afárá náà láàrin iṣẹju díẹ̀,” o sọ.

Nígbàtí ó ń sọ̀rọ̀ lórí bí o ṣé ṣé pàtàkì fún àwọn awakọ̀ látí bọwọ fún òfin ojú popo, Mínísítà náà sọ pé, “ inú Ààrẹ yóò dùn láti ríi pé àwọn awakọ̀ ṣé jẹ́jẹ́ lójú pópó, pàápàá jùlọ ní àkókò Kérésìmesì yìí àti àkókò ọdún tuntun.

A kò tíì parí iṣẹ́ lórí afárá yíì, ṣùgbọ́n a yọ sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ lórí afárá Niger àkọkọ́. Ní Ọjọ karundinlogun, Oṣù Kíní Ọdún 2023, a yóò ṣé ìyípadà fún àwọn tí n bọ̀ látí ila-oorun sí ìwọ̀-oòrùn. ”

Lórí ọrọ owó ibodè, Mínísítà tẹnumọ pé ki wọ́n má sàn owó kánkan fún ẹnikẹ́ni ní gbàgede ibodè náà, nítori pé o wà lọfẹ.

Ni apá tirẹ̀, Alàkóso tí Federal Road Safety Corps, Ẹka tí Ìpínlẹ̀ Delta, Ọgbẹni Bassey Esiet, sọ pé àwọn yóò ṣé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ilé-iṣẹ́ agbofinro látí ríi dájú pé igbokegbodo ọkọ ń lọ́ ní irọwọ lẹba afárá Niger àkọkọ́. O sí gbà àwọn awakọ̀ ní iyànjú láti yàgò fún èrè asapajude, kí wọ́n sì bọwọ fún òfin ojú pópó.

Mínísítà náà wá ṣé àyẹwò pẹ̀lú Kọmisana fún Àwọn iṣẹ́ (Awọn opopona ati Ilu), Noel Omodon; Adarí iṣẹ́, Federal Ministry of Works and Housing àtí Onimọ-Ẹrọ fún iṣẹ àgbéṣe, Oluwaseyi Martins; Alakoso ti Federal Road Safety Corps (FRSC) Ẹka Ìpínlẹ̀ Delta, Bassey Esiet, àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ mìíràn àtí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ mìíràn.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button