Take a fresh look at your lifestyle.

Omíyalé Ba Dúkìá Jẹ́ Tí Ọ̀pọ̀ Ènìyàn Sì Pàdánù Ẹ̀mí Ní Orílẹ̀ Èdè DR Congo

0 299

Kò dín ní ènìyàn márùn ún dín lọ́gọ́ta (55) tí ó pàdánù ẹ̀mí, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn fi ara pa nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá sì sòfò látàrí ẹ̀kún omi nígbà tí òjò ńlá kan rọ̀ ní Kinshana, olú ìlú orílẹ̀ èdè Congo.

 

Gẹ́gẹ́ bí mínísítà Jean Micheal Sama Lukonde se sọ, ìjọba ti ń se akitiyan láti yanjú ìsòro náà pẹ̀lú ìkúnlọ́wọ́ àwọn ará ìlú, sùgbọ́n ẹ̀kún omi náà pọ̀ tí ó sì ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ pẹ̀lú pípàdánù ẹ̀mí àwọn ènìyàn. Akitiyan ńlọ lọ́wọ́ láti se àwárí òkú àwọn ènìyàn.

 

Aarẹ Felix Tshisekedi, ẹni tí ó ń kópa lọ́wọ́ níbi àpérò ilẹ̀ adúláwọ̀ ní ìlú Washinton, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti ráńsẹ́ ìkẹ́dùn rẹ látàrí àwọn tí ó pàdánù ẹ̀mí wọn, ó sì se ìlérí ìgbésẹ̀ ìjọba ní kíákíá láti pinwọ́ ìsòro náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button