Aarẹ Muhammadu Buhari sọ pé àwọn ọ̀dọ́ ni ọ̀la orílẹ̀ èdè wa, àtipé ìjọba fi ọwọ́ bàbàrà mú títán ìsòro wọn.
Ó sọ eléyìí ní Washinton DC nígbà tí ó ń kí akọ̀wé àgb̀a ti àjọ Abu Dhabi, Sheik Al-Mahfoudh Bin Bayyah àti igbákejì rẹ̀ káàbọ̀, pẹ̀lú alagba Bob Roberts ti orílẹ̀ èdè America tí wọ́n se àbẹ̀wò síi. Ààrẹ sọ pé, iṣẹ́ àjọ náà fún ìpolongo ìbásepọ̀ láàrin ẹlẹ́sìn-mẹ̀sìn se pàtàkì sí àgbáyé àti sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Akọ̀wé àgbà àjọ náà sọ pé, àwọn wá láti pe ààre fún fífi àmì ẹ̀yẹ àjọ náà ( Abu Dhabi Foundation) dá a lọ́lá fún àseyọrí rẹ̀ nípa ètò ààbò àti àlàáfíà àwùjọ.
Leave a Reply