Angola tí gbalejo àpéjọ OACPS ẹlẹẹkẹwaa irú rẹ̀ (10th Organisation of Africa, Caribbean, and Pacific group of states, OACPS) èyítí o dúró fún àwọn ọkandinlọgọrin (79) orílẹ̀-èdè.
Ìròyìn sọ pé ìpàdé náà tó wáyé ní ọjọ́ Ẹtì ní Olú-ìlú Angola tí Luanda ní àpéjọ kẹwàá ìrù rẹ̀ tí àwọn Olùdarí Orílẹ̀-èdè tí OACPS tí ṣé àkọ́kọ́ nínù mẹta tí Angola yóò gbalejo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Alàkóso ìgbìmọ̀ náà.
Àkòrí fún ìpàdé ti ọdún yìí ní “Three Continents, Three Oceans, a Common Destiny: Building a Resilient and Sustainable OACPS”
Sibẹsibẹ, Angola pinnu pé o yẹ kó dojukọ àwọn òun tó kọnilominu bìí ìyípadà oju-ọjọ àtí ìṣàkóso tó dára, pẹ̀lú ìkọ ìbàjẹ́. Èyí dùn mọ́ orílẹ̀-èdè Maldives nínù nítorí ipenija tí wọ́n kojú lórí ìyípadà ojú-ọjọ́
Gẹ́gẹ́ bíí ilé ifowopamọ àgbáyé ṣé sọ, “pẹ̀lú ìwòyè, omí òkun yóò kùn sí ní ọgọrùn ìgbà ní ọdún 2100 tó sí lè bò gbogbo ìlú náà mọ́lẹ̀”
Orílẹ̀-èdè erékùṣù náà darapọ̀ mọ́ OACPS ní ọdún yìí ṣùgbọ́n o ní ìrètí látí ní ló àtìlẹ́yìn àgbáyé látí kojú irọkẹ̀kẹ náà.
Alàkóso European Union, Charles Michel, àti Akọ̀wé Gbogbogbò United Nations, Antonio Guterres ní a n’ireti látí wá sì àpéjọ náà.
Ní ìparí, gbogbo àwọn olórí ìlú ní a tí ní ìrètí látí f’ọwọ́ sí ìkéde àpéjọ náà.
Lekan Orenuga
Leave a Reply