Àwọn Olùdarí tí Orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà tó pàdé ní olú-ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọjọ́ Àìkú béèrè pé kí ìjọba Mali tú àwọn ọmọ ogún mérin dín làádọ́ta orílẹ̀-èdè Ivory Coast tó wà ní ìgbèkùn wọ́n láti Oṣù Keje sílẹ̀ tàbí kojú àwọn ìpenija àwọn ìjọba Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà.
“A béèrè lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ Mali látí tú àwọn ọmọ ogún Ivory Coast sílẹ̀, o pẹ́ jú Ọjọ́ kíní Oṣù Kíní, Ọdun 2023,” Omar Touray, Alága tí ẹgbẹ́ náà sọ fún àwọn oníròyìn.
Tó bá kùnà, ECOWAS yóò gbé àwọn ìjìyà oriṣiríṣi kò wọ́n lójú, ọkàn nínú àwọn aṣojú Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà sọ ní abẹ́ aṣọ.
Touray tún sọ pé ECOWAS ní ẹtọ látí ṣé ìjìyà tòótọ́ tí àwọn ọmọ-ogun náà kò bá gbà òmìnira pàdà nì ọjọ́ kíní Oṣù Kíní ọdún tó ń bọ̀.
Ààrẹ Togo Faure Gnassingbé, tó wà laarin Mali ati Ivory Coast lórí aawọ yìí, yóò lọ sí Mali látí “béèrè” ìtusílẹ̀ àwọn ọmọ-ogun náà, aṣojú kàn ṣàfikún.
Mali tí ń bá Côte d’Ivoire ati ECOWAS jà látí ìgbà tó tí mú àwọn ọmọ ogún Ivorian láti ọjọ́ kẹwàá Oṣù Keje nígbàtí wọ́n dé Bamako tí wọ́n sì fi Mẹta nínú wọ́n sílẹ̀.
Côte d’Ivoire àti UN sọ pé àwọn ọmọ-ogun wọ̀nyí ló wà látí kópa nínú ètò ààbò tí orílẹ̀-èdè Germany ń ṣé ní Mali. Ṣùgbọ́n Bamako sọ pé àwọn kà wọ́n mọ “Ẹsìn o kọ̀ kù” tó wá láti dá ojú ààbò ìlú àwọn rú.
Lekan Orenuga
Leave a Reply