Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Tí Bẹ̀rẹ̀ Ìsinmi Ìbímọ Fún Àwọn Òṣìṣẹ́ Ìjọba Ọkùnrin

0 368

Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí bẹ̀rẹ ìsinmi lẹnu iṣẹ́ ọlọjọ mẹrinla fún àwọn ọkùnrin òṣìṣẹ́ ìjọba tí ìyàwó wọn bímọ.

Èyí ní yóò bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́bí àkọlé ìwé àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n pé àkọlé rẹ̀ ní “àkọsílẹ̀ ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu ìṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ àtí Ifọwọsi ìsinmi àwọn Bàbá òṣìṣẹ́ ìjọba” (Computation of Leave Based on Working Days and Approval of Paternity Leave in the Public Service) ní ọjọ́ kàrúndínlọ́gbọ́n Oṣù kọkànlá ọdún 2022.
Ọdún tó kọjá ní ìgbìmọ̀ Aláṣẹ Orílẹ̀-èdè yìí fọwọ́sí ẹtọ ìsinmi àwọn bàbá ọlọjọ́ merinla fún àwọn òṣìṣẹ́ Ọkùnrin.

Ọgá àgbà òṣìṣẹ́ ìjọba tí Orílẹ̀-èdè yìí Folasade Yemi-Esan, sọ pé ìgbésẹ náà wà ní ìbámu pẹlú àwọn ìpèsè òfin ilé iṣẹ ìjọba, tí àtúnṣe 2021 sọ pé ìṣirò gbogbo ìsinmi lẹ́nu ìṣẹ́ yóò dá lórí ọjọ iṣẹ́ tí kòsí gbọdọ jù ẹẹkan lọdún méjì fún ọmọ mẹ́rin.


“fún ti ìdílé tí òṣìṣẹ́ Ọkùnrin tó gbà ọmọ tí kojú oṣù mẹ́rin tọ́, òṣìṣẹ́ náà yóò ní anfààní bákannáà láti gbádùn ìsinmi Bàbá fún àkókò ọjọ́ iṣẹ́ mẹrinla,” Yemi-Esan sọ.

Nitorinà ìwọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn nkán tuntun tó wà nínú PSR tí wọ́n ṣẹṣẹ fọwọ́sí nípasẹ̀ ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba,” o fi kún.

Nígbà tí wọ́n ní kí o ṣàlàyé ní kíkún sí nípa ìsinmi ìbímọ́ bàbá àti àwọn tó tóótun láti jàǹfààní nínú rẹ̀, Yemi-Esan sọ pé, “Ìsinmi baba jẹ́ ìsinmi tí wọ́n fọwọ́ sí fún àwọn ọkùnrin, nígbà tí ọkọ tàbí aya wọn bá ti bí ọmọ tuntun, tàbí bí ọkọ àti ìyàwó sì ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ọmọ tọ́ tí kò tíì pé oṣù mẹ́rin, lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà ní ẹ̀tọ́ sí ìsinmi baba fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́rìnlá [14].

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button