Aláatìlẹyìn ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti South African, ANC àti ẹgbẹ́ South Africa’s Communist Party ti se Ìwọ́de ní ìta ilé ẹjọ́ ti òfin ní ìlú Johannesburg.
Àwọn olùwọ́de náà wọ́de láti tako ìdásílẹ̀ olùtakò ajààngbara ẹlẹ́yàmẹyà Chris Hani, tí wọ́n pa ní ọdun1993.
Janusz Walus ní wọ́n dájọ́ ikú fún sugbon tí orí kó yọ nígbà tí ìfòpin sí ètò ìdájọ́ ikú ní ọdún 1994 kó orí rẹ̀ yọ nípa yiyi ẹjọ́ ikú padà sí ẹ̀wọ̀n gbére.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply