Àjọ tí ó ń gbógun ti lílo òògùn olóró ní orílẹ̀ èdè wa National Drug Law Enforcement Agency, NDLEA, ti fi ọwọ́ òfin mú agbénú òkùnkùn sebi kan, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (57), Lawal Lateef Oyenuga ní òpin ọ̀sẹ̀. Ó gbé òògùn olóró tí ó tó irinwó gíráàmù (400grm) tí ó sì ṣe é lọ́jọ̀ sínú bàtà lọ sí Jeddah, ní orílẹ̀ èdè Saudi Arabia.
Agbenusọ àjọ náà, ọ̀gbéni Fẹmi Baba-Fẹmi ni ó sísọ lórí ọ̀rọ̀ náà wípé àríwòye àti ìwà ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ni ó jẹ́ kí ọwọ́ tẹ okùnrin onísẹ́ láabi kan, wasiu Gbọlahan ti wọ́n mọ̀ sí (teacher) tí ó jẹ́ baba ogun fún àwọn onísẹ́ láabi náà.
Àjọ náà fi àrídájú hàn pé òhun yóò máa ṣiṣẹ́ takun-takun láti ríi dájú pé òpin dé bá lílò òògùn olóró ní àwùjọ wa.
Leave a Reply