Ilé ìṣẹ́ Ẹwọn South Africa sọ pé àwọn yóò takò ìdájọ ilé-ẹjọ́ kàn tó ràn Àárẹ̀ tẹlẹ rí Jacob Zuma pàdà sí tubu.
Ilé ìṣẹ́ Àtúnṣe (Department of Correctional Service DCS) sọ pé “Nígbàtí o farabalẹ kà ìdájọ́ náà, Àwọn ilé ìṣẹ́ Àtúnṣe náà ní ìdánilójú pé ilé-ẹjọ́ mìíràn lé dá ẹjọ́ tó yàtọ.”
Nibayii, ilé-ẹjọ́ gígajùlọ tí pàṣẹ ní ọjọ́ Ajé pé kí Ààrẹ tẹlẹ náà pàdà sí ẹ̀wọn lẹyìn tó fí ìdí ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ àkọ́kọ́ múlẹ pé itusilẹ rẹ̀ láàkọ́kọ́ kò bá òfin mú.
Ẹní ọgọ́rin ọdún náà ní wọ́n dàjọ́ oṣù mẹẹdogun fún ní ọdún tó kọjá fún bí o ṣé kọ̀ láti jẹrìí làkókò ìwádìí ìwà ìbàjẹ́ kàn.
Àmọ́, wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́yìn oṣù méjì tí o fi wà lẹ́wọ̀n, lẹ́yìn tí àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ ti sọ pé ó ní àìsàn kan tó lè máa gbẹ̀mi rẹ̀, ó sì nílò ìtọ́jú tí Ilé Iṣẹ̀ Àtúnṣe kò lè pèsè fún nínú ẹ̀wọ̀n.
Lekan Orenuga
Leave a Reply