Ẹ Fọwọ́ Sowoọ́ Pọ̀ Pẹ̀lú Ilé Iṣẹ́ Tó ńṣe Àtúnrọ Ohun Èlò Àlòkù: Mottainai Recycling Ltd Ké Sí Ìjọba Àpapọ̀
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti rọ gbogbo olùgbé ipinlẹ náà láti tẹwọ gbà ìgbé ayé ṣíṣe atunlo ike, páálí àti àwọn ohun èlò aloku míràn.
Atẹjade eléyìí tí Komisana fún ìròyìn, Àṣà àti Ìrìn Àjò Afe, Omowe Wasiu Olatubosun fi síta ló sàlàyé lórúko ile iṣẹ tó n ri sí ṣíṣe atunro áwọn ohun èlò aloku bíi ike àti páálí sí nkan míràn, Mottainai Recycling Ltd wípé, ṣíṣe atunlo awọn ohun èlò aloku yóò mu adinku bá itankalẹ idọti.
Ọgbẹni Adey Adewuyi tíì ṣe Alakoso ilé iṣẹ Mottainai Recycling Ltd lo rawọ ẹbẹ sí gbogbo olùgbé ìpínlè Ọ̀yọ́ láti fi ọwọ s’owo pọ pẹlú ìjọba ni ònà àti gbógun ti ìwà idọti to n fi ojoojumọ gbilẹ, ni pataki jùlọ laarin igboro ilu Ibadan.
Bákan náà ni Adewuyi rọ ìjọba àpapọ ati àwọn ìjọba ìpínlè yòókù lati fi ọwọ s’owo pọ pẹlú ile iṣẹ tó n ri sí atunro ohun èlò aloku lati gbogun ti idọti to n di àwọn ojú iṣan omi eléyìí to n fa omi yalé ati awọn ipenija míràn láwùjọ.
Adewuyi, ẹni tí o woye pé ọnà tí idọti fi n pọ sí jake jado orilẹ èdè Nàìjíríà ti fi hàn gbangba pé gbogbo èèyàn ló ní láti dá sí ọrọ tó wà nílé yìí láti kojú ipenija eléyìí tí idọti inú omi àti afẹfẹ leè mú wá sí àgọ ara ọmọnìyàn.
Abiola Olowe
Ìbàdàn.
Leave a Reply