Ọkọ̀ òfuurufú kàn pẹ̀lú àwọn ènìyàn mẹ́tàlélógójì (43) ló kọlu adágún odò Victoria ní Tanzania nígbà tó ń sún mọ́ Bukoba ní ìwọ̀ oòrùn àríwá. Ìjàmbá náà ló wáyé nítorí ojú ọjọ́ tí kó dára
Ọkọ̀ òfurufú French-Italian-Built tí ATR 42 tí àwọn oníṣe àdáni tó tóbi jù “Precision Air,” ní Tanzania lábẹ́ Kenya Airways èyítí o ń kó àwọn onírin àjò lọ́ sí àwọn ibí ìgbafẹ́ bìí Serengeti National Park ati Zanzibar Archipelago.
Àwọn ènìyàn mẹ́tàlélógójì (43), bìí àwọn arinrin-ajo mọkandinlogoji (39), àwọn awakọ̀ méjì (2) àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ méjì, ló wà nínú ọkọ̀ òfurufú láti olú-ìlú Dar es Salaam sí Bukoba.
Àwọn olùgbàlà ní ọsán ọjọ́ Àìkú ṣiṣẹ́ láti gbà àwọn èrò inú ọkọ àti ọkọ̀ òfurufú naa kúrò nínú omí.
Alákóso àwọn ọlọ́pàá ẹkùn Kagera jẹri sí ìṣẹ̀lẹ̀ naa.
Àwọn ènìyàn mẹrindinlọgbọn (26) ni wón ti doola ẹ̀mí wọ́n àtí gbé wọ́n lọ́ sí ilé ìwòsan kàn.
Ààrẹ orílẹ̀-èdè Tanzania, Samia Suluhu Hassan tí kẹdun fún àwọn tí ìjàmbá ọkọ náà ṣẹlẹ sí, o sí ní kí àwọn ènìyàn fi ọkàn bálẹ̀ bí iṣẹ́ ìgbàlà náà ṣé ń tèsíwájú.
Irúfẹ́ Ìjàmbá náà ló tí wáyé ríi ní bí ọdún márún sẹyìn níbí tí ènìyàn mọkanla ti pàdánù ẹ̀mí wọ́n nígbà tí Ọkọ òfurufú ilé iṣẹ́ Safari kàn já lúlẹ̀ ní àríwá Tanzania.
Lekan Orenuga
Leave a Reply