Mínísítà ètò ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè ìgbèríko, ọ̀mọ̀wé Muhammewd Abubakar ti fi dá gbogbo ọmọ Nàìjíríà lójú pé kò ní sí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ ní ọjọ́ iwájú.
Abubakar fi àrídájú náà léde nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin lórí ìsúná owó tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ẹka ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè ìgbèríko , èyí tí ìgbìmọ̀ ẹka ètò ọ̀gbìn ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin se agbátẹrù rẹ̀.
Àríwòye wà pé ọ̀wọ́n oúnjẹ yóò sẹlẹ̀ ní ilẹ̀ adúláwọ̀ nítorí ìdáwọ́dúró kíkó oúnjẹ wọlé látàrí ogun tí ó ń sẹlẹ̀ láàrin orílẹ̀ èdè Russia àti Ukraine, sùgbọ́n Minisita náà fi dáwa lójú pé, ìjọba ti gbáradì láti dènà ọ̀wọ́n oúnjẹ.
Leave a Reply