Take a fresh look at your lifestyle.

Ọ̀mọ̀wé Isiaka Kolawole Di Olùdarí Ìgbìmọ̀ Ìpolongo Ìbò Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

0 471

Ẹgbẹ òṣèlú All Progressive Party, APC ni ìpínlè Ọ̀yọ́ fi ìgbìmò ìpolongo ibo fún ètò ìdìbò ọdún 2023 lọlẹ nígbàtí ẹgbẹ náà fi dá àrà ìlú lójú wípé òun ṣetan láti bẹrẹ ìpolongo ibo eléyìí tí kò ní mu jagidijagan lọwọ.

Ẹni tíì ṣe Oludije du ipò gómìnà ninu ẹgbẹ òṣèlú náà, Olóyè Teslim Kolawole Folarin lo ti fí àsìkò náà ké sí ìjọ bá tó wà lóde labẹ àkóso Gómìnà Seyi Makinde láti wá woroko fi s’ada lórí àwọn kolorosi tó n ba àwọn patako àti ìwé alemogiri fún ìpolongo ibo ẹgbẹ́ òṣèlú APC jẹ láti tọwọ ọmọ wọn bọ asọ.

Olóyè Teslim Folarin nígbà tí o n ba àwọn ọmọ ẹgbẹ ati àwọn aṣáájú ẹgbẹ tó péjú sọrọ ló sàlàyé fún ẹni tí ẹgbẹ náà yan gẹ́gẹ́ bíi Olùdarí Gbogboògbò fún ìgbìmò ìpolongo ibo Ààrẹ ati Gómìnà fún ètò ìdìbò ọdún tó n bọ (DG, Oyo State APC Presidential and Governorship Campaign Council) Ọmowe Isiaka Kolawole láti ṣe ìpàdé ní kíákíá pẹlú gbogbo ìgbìmò ìpolongo ibo ki wọn le bẹrẹ iṣẹ leye-o-soka.

Bákan náà ni Olóyè Folarin fi dá gbogbo èèyàn ìpínlè Ọ̀yọ́ lójú wípé ti wọn ba fi ibo wọn gbé oun wọlé gẹgẹ bíi Gómìnà nínú ètò ìdìbò ọdún tó n bọ wípé ìṣèjọba òun kò ní kó àwọn alágbe àti oníbárà lọ sí àgbègbè Òkè-Ogun gẹgẹ bí ìjọba tó wà lóde ṣe la kalẹ, sugbọn òun yóò rí dájú pé ọrọ ajé ipinlẹ Ọ̀yọ́ ru gogo síi nípa mímú igbega àti irọrun dé bá iṣẹ àgbẹ ní agbègbè náà kí ounjẹ lẹ pọ yanturu. O sì tún fi dá wọn lójú pé ìṣèjọba òun yóò tún rí dájú pé eto ààbò tó péye wa fún èmí àti dukia gbogbo olùgbé ìpínlè Ọ̀yọ́.

Nínú ọrọ tirẹ, Ọmowe Isiaka Kolawole sàlàyé wípé òun dupẹ lọwọ Olóyè Teslim Folarin tíì ṣe oludije du ipò gómìnà àti gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ fún bí wọn ṣe fi ohùn ṣọkan lati fa òun kalẹ gẹgẹ bíi Olùdarí Gbogboògbò fún ìgbìmò ìpolongo ibo Ààrẹ ati Gómìnà fún ètò ìdìbò ọdún tó n bọ (DG, Oyo State APC Presidential and Governorship Campaign Council). O sì sọ di mímọ pé òun ti ṣetán láti ṣe ojúṣe náà láti rí wípé ẹgbẹ òṣèlú APC ni ìpínlè Ọ̀yọ́ jáwé olubori nínú ìdìbò gbogbo-gbòò ọdún tó n bọ.

Bákan náà ni Ọmowe Kolawole tún sàlàyé síwájú síi pé òun ṣetán láti gba ìmọ̀ràn àti ìtọ́nisọ́nà lọwọ àwọn àgbààgbà àti ọmọ ẹgbẹ fún àṣeyọrí eto ìpolongo ibo to n bọ, nígbà tí o rawọ ẹbẹ sí gbogbo àwọn ìgbìmò ìpolongo ibo to le diẹ ní Ègbérun Mẹta (3,333) fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn ki ẹgbẹ òṣèlú APC le jáwé olubori nínú ìdìbò gbogboògbò ọdún 2023.

O wa fi àsìkò náà se iranti àwọn adari ẹgbẹ APC ni ìpínlè Ọ̀yọ́ ti wọn ti di olóògbé bíi: Gómìnà Lamidi Adesina; Gómìnà Abiola Ajimobi; Gómìnà Adebayo Alao-Akala ati gbogbo àwọn tí wọn ti ṣe takuntakun ninu ẹgbẹ náà ni ìgbà ayé wọn, nígbà tí o gbà l’adura ki Ọlọrun tubọ máa tẹ wọn sì afẹfẹ réré.

Lára àwọn to tún péjú nibe ní alága ẹgbẹ́ APC ni ìpínlè Ọ̀yọ́, Isaac Omodewu, ati àwọn aṣáájú ati àgbààgbà nínú ẹgbẹ náà.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button