Take a fresh look at your lifestyle.

Italy:Ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 280

Ènìyàn mẹ́rin ló ti  fara gbọgbẹ́ tí ẹnìkan sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ níbi ìgúnbẹ tó ṣẹlẹ̀ ní ilé-ìtajà kan ní orílẹ̀-èdè Italy.

Ìròyìn sọ pé ìjàm̀bá náà ṣẹlẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́bọ̀, ní ilé-ìtajà Carrefour, ní gbàgede ìtajà kan ní Milan.

Ẹni tí ó ń gbowó ọjà lọ́wọ́ àwọn alábàárà,tí ó jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí arákùnrin kan kojú àwọn ènìyàn ní Assago.

Lára àwọn tí ó farapa ni, Pablo Mari,ọmọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Arsenal, tí ó yá síta fún Monza, ní orílẹ̀-èdè Italy.

Olùfura si tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndín-láàdọ́ta, ti wà ní àtìmọ́lé báyìí.Àwọn agbófinró ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò wá látọ̀dọ̀ àwọn oní jàgídíjàgan.

Ìròyìn sọ pé olùfurasí náà jẹ́ ẹni tí ó ní ààrùn ọpọlọ.

Wọ́n ní ó kàn bẹ̀rẹ̀ sí ní máa gún àwọn ènìyàn lọ́bẹ káàkiri ni,ní déédé agogo mẹ́rin ààbọ̀,ní Carrefour,ní ilé-ìtajà àdúgbò kan.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button