Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ti rọ àwọn alámójútó ààbò Nàìjíríà àti àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè láti ṣọ́ra nítorí pé ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí, ó sọ pé ó ṣe pàtàkì láti yàgò fún ìbẹ̀rùbojo.
Nínù ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan, ààrẹ rọ àwọn ọmọ orílè-èdè láti fọkàn balẹ̀.
Ó sọ pé: “Àwọn àyípadà tó débá ìmọ̀ràn lórí ìrìn-àjò láti ọ̀dọ̀ ìjọba Amẹ́ríkà àti UK, kí wọ́n máá jẹ́ kí ó fa ìjayà.
Ààrẹ wá fi ọkàn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè balẹ̀ pé ìgbésẹ̀ ti wà láti kojú èyíkéyìí ìgbìyànjú àwọn oníjàgídíjàgan tó bá fẹ́ ṣèjàm̀bá àlàáfíà olú-ìlú àti àwọn agbègbè mìíràn ní orílẹ̀-èdè.
Leave a Reply