Take a fresh look at your lifestyle.

South Africa Fèsì Sí Irọkẹ̀kẹ Ẹrù Tí AMẸRIKA Ṣé

0 425

Ìgbìmọ̀ Alàkóso orílẹ̀-èdè South Africa tí fí dá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè South Africa lójú pé àwọn ilé-iṣẹ́ Agbofinro ń ṣàkíyèsí èyíkéyìí àwọn irọkẹ̀kẹ ewu sí gbogbo olùgbé orílẹ̀-èdè.

Ìdánilójú náà jẹ́ yọ lẹyìn tí Ilé-iṣẹ́ Amẹ́ríkà gbé itaniji ààbò sí orí Ayélujára fún àwọn àrà ìlú rẹ̀ ní South Africa pé àwọn agbebọnrin afẹmiṣofo Onijagidijagan “le gbèrò láti ṣé ikọlù sí àwọn àpéjọpọ̀ nlá tí àwọn ènìyàn” ní Sandton ní àgbègbè Johannesburg.

Nínú àlàyé kàn, Alàkóso orílẹ̀-èdè náà sọ pé: “O jẹ́ ojúṣe tí àwọn ẹlẹṣọ ààbò South Africa láti ríí dájú pé gbogbo olùgbé orílẹ̀-èdè wà ní ifọkanbalẹ,” àlàyé náà sọ.

O sọ pé àwọn ilé-iṣẹ́ agbofinro n ṣé abojuto èyíkéyìí irọkẹ̀kẹ ewu tó lè wà fún àwọn ará ìlú àti orílẹ̀-èdè.
Tó bá nilo láti sọ fún gbogbo àwọn olùgbé nípa èyíkéyìí irọkẹ̀kẹ tó súnmọ́, ìjọ̀ba orílẹ-èdè ní yóò jẹ́ àkọ́kọ́ láti sọ” àlàyé náà ṣàfikún.

Lekan orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button