Ààrẹ Muhammadu Buhari tí bú ẹnu àtẹ lù ikọlù tó ṣẹṣẹ wáyé ní ìpínlẹ̀ Benue.
Nínú ọrọ rẹ̀, Ààrẹ sọ pé kò sí itẹwọgbà fún ẹnikẹ́ni láti gbà ẹmi ẹnìkejì yálà darandaran ní tàbí àgbẹ̀.
“Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ kọlù ẹnikẹ́jì nítorí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ní kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbẹ̀san lára àwọn ẹlòmíràn nítorí àìṣèdájọ́ òdodo tí wọ́n ṣe sí wọn. Ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá bà yóò fí ojú wina ìdájọ òdodo.
“Bákannáà ní kó sí itẹwọgbà fún ẹnikẹ́ni láti gbà ẹmi àwọn tí wọ́n wà lẹnu iṣẹ́ wọ́n gẹ́gẹ́ bí Agbofinro àti àwọn Òṣìṣẹ́ Ìjọba. Ìjọba yóò ṣé ìdájọ lórí ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá bà.” o sọ.
Ààrẹ náà ṣé ìlérí àtìlẹ́yìn kíkún láti ṣé ìrànwọ́ fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Benue, Samuel Ortom, àti àwọn ará ìlú pẹ̀lú àwọn òun èlò làti ṣàwarí àwọn oníṣe ìbí náà.
“A gbọ́dọ̀ máa rántí ṣáájú pé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní gbogbo wà nígbà tí irú àwọn àjálù báyìí bá ṣẹlẹ̀.
Lọpọ ìgbà ní òṣèlú a máa dínà ìlọsíwájú fún orílẹ̀-èdè wà tí a tún máa pin wà ní yà gẹ́gẹ́bí àwọn tí a fí ṣé aṣojú aláṣẹ awọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí,” o sọ.
Ó fi kún un pé ojúṣe orílẹ̀-èdè náà ni láti ṣe gbogbo òun tí wọ́n lè ṣe láti borí ìyapa, kí wọ́n sì kóra wọ́n jọ.
Lekan orenuga
Leave a Reply