Orílẹ̀ èdè Ethiopia ti fi òfin de fífún àwọn tí ó ń kó ọjà wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè ní àǹfààní láti gba owó ilè òkèèrè lójúnà àti dènà kíkó àwọn ohun èlò tí kò se ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè náà ní ànfààní. Eléyìí yóò mú kí owó tí orílẹ̀ èdè náà ń pamọ́ fún ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì gbèrú síi.
Lára àwọn ohun èlò tí wọ́n fi òfin de kíkó wọlé rẹ̀ ni ọtí, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, oúnjẹ, òògùn òyìnbó, èrò ìja ìlera, abùradà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ orílẹ̀ èdè náà ti fi léde pé, òun ti ti akoto ìfowópamọ́ tí kò dí ní irinwó pa, nípa lílò wọn ní ọ̀nà èrú láti kó àwọn ohun èlò tí kò se ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè náà ní ànfààní wọlé.
Leave a Reply