Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí ó wà ní ìlú Abuja ti fa igi lé ẹ̀sùn ìwà adàlúrú tí ìjọba àpapọ̀ fi kan olórí ajàjàgbara fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra. Eléyìí tí ó wáyé ní ọjọ́bọ̀. Ilé ẹjọ́ náà dá a sílẹ̀ ní ẹni tí kò mọ ọwọ́ mọ ẹsẹ̀ níbi ẹ̀sùn méje tí wọ́n fi kàn-án.
Ilé ẹjọ́ fi léde pé, ìjọba àpapọ̀ ń tẹ̀ òfin lójú mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n fi tipá-tipá dá ọ̀gbẹ́ni Kanu padà sí ilẹ̀ Nàìjíríà láti orílẹ̀ èdè Kenya.
Ó tún fi ìdí ìdájọ́ rẹ̀ múlẹ̀ pé, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wà lára orílẹ̀ èdè adúláwọ̀ tí ó fi ọwọ́ sí ìwé òfin ní ọjọ́ kejìdílọ́gbọ̀n osù kẹfà ọdún 2022 léyìí tí ó tako irúfẹ́ ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gbé láti dá ọ̀gbẹ́ni Kanu padà .
Leave a Reply