Orílẹ̀-èdè Mozambique ti ri Ààrùn Ọ̀bọ àkọ́kọ́ he lati ìgbà tí àjọ World Health Organization, WHO, ti polongo rẹ̀ faye gbọ́ lati osù kárùn ún.
Ọkùnrin kan ni won ti se àyẹ̀wò rẹ ní Olu ilu ni Maputo pé o ti lùgbàdì àìsàn náà. Awọn eleto ilera fi kun wipe akọsilẹ ìrìnàjò to se kakiri wà fún ùn.
Igbiyanju lati ri gbogbo awọn to ti fara kan kakiri sí n tẹsiwaju bi awọn eleto ilera se sọ.
Àìsàn Monkeypox náà tí jẹyọ jade ni Orilẹ̀-èdè tó súnmọ́ Mozambique bíi South Africa ati Malawi bi ìròyìn se ròó.
Àìsàn náà wá láti ara kòkòrò to wa láti ara Monkeypox, ara ìbátan rẹ “smallpox” tiko lagbara too, sugbon lilugbadi àìsàn eleyi kéré gégébí àwọn ọjọgbọn se sọ.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply