Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Gómìnà Nínú Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC SE Ìpàdé Pọ̀ Pẹ̀lú Àjọ Òṣìṣẹ́ Ti Ẹgbẹ́ Oṣèlú APC

0 247

Gómìnà méfà, láti inú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ati awọn ọmọ ẹgbẹ́ olupolongo ìbò aarẹ
nínú ẹgbẹ́ kan naa ti wa ninu Ipade pẹlu Àjọ Òṣìṣẹ́ Ti ẹgbẹ́ APC . Ipade náà n waye ni gbọ̀ngàn ìpàdé ti ẹgbẹ òṣèlú APC ní Abuja.
.

Alága gbogbo gbò fún ẹgbẹ òṣèlú APC, Senetọ̀ Abdullahi Adamu to sọrọ nibi Ipade náà sọ wípé idi tí ìpàdé náà yóò fi waye ni lati sọrọ nípa aseyori ẹgbẹ náà nínú ìbò odun to ń bọ. O sọ pé ko leè sí aseyege nínú ìbò láì sí akitiyan awon Gomina ti won jẹ adari ni ipinlẹ̀ kaluku wọn.

Àwọn tó péjú síbi ìpàde náà nìwọ̀nyí:
Plateau State, Simon Lalong, Jigawa Governor Abubakar Badaru, Kano State Governor, Abdullahi Ganduje, Nasarawa Governor, Abdullahi Sule, Niger state governor, Abubakar Sani Bello, Zamfara Governor, Bello Matawalle, Ondo Governor, Rotimi Akeredolu àti igbákejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Borno state, Umar Kadafur.

Àwọn tó tún pejọ sibẹ ni Gomina tẹlẹ ti ipinle Edo, Adams Oshiomhole, adari tẹlẹ ti Nigeria Ports Authority, Hadiza Bala Usman ti awọn mejeeji jẹ igbakeji Adari ẹgbẹ òṣèlú olupolongo ìbò ti APC.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button