Take a fresh look at your lifestyle.

Ajíbádé Yóò Ṣáájú Ikọ̀ Falcons Nígbàtí Wọ́n Bá Dojúkọ Nadeshiko Ní Ìlú Kobe

0 297

Ògbóntarìgì agbábọ́ọ̀lù Ajíbádé yóò ṣáájú Ikọ̀ tí àwọn Obìnrin orílẹ̀-èdè yìí nígbà tí wón bá fesẹ̀wonsẹ̀ pẹ̀lú ojúgbà wọn láti orílè-èdè Japan ní ọjó Ọjọ́rú ní Ìlú Kobe.

Ara ẹlẹṣẹ̀ ayò, Onome Ebi ṣẹṣẹ n bọ̀ sipò látàrí ifarapa tó ní WAFCON to waye ni Morocco ni oṣù keje, Asisat Oshoala náà kòní leè kópa fún ìdíje yií bakanna ni Kobe.

Agbábọ́ọ̀lù Ajíbádé ti gbá bóòlù léèmeta sinu awọn ní àtijó ni Orile-ede Morocco, ti o pẹlu aseyege won pẹlu Orile-ede Cameroon ni ipele quarter-finals tó jẹ kí wọn  peregede  fun FIFA Women’s World Cup finals ti yóò wáyé ní orílé èdè Australia àti New Zealand ni ọdún tó ń bọ̀.

Asọ́lé àkọ́kọ́ Chiamaka Nnadozie ti wa ni ṣẹpẹ́, pẹlú adeyinmu bi,  Michelle Alozie, Osinachi Ohale, Ashleigh Plumptre ati Glory Ogbonna, àwọn agbábọ́ọ̀lù bíi Ngozi Okobi-Okeoghene, Christy Ucheibe and Deborah Abiodun, and forwards Ifeoma Onumonu àti Uchenna Kanu, Jumoke Alani ati Akudo Ogbonna, midfielders Peace Efih àti Esther Onyenezide, ati forwards Amanda Uju Mbadi ati Flourish Sebastian ati asọ́lé Peace Obidinma ni wọ́n ti péjú pésẹ̀.

Abiodun, Obidinma, Alani, Onyenezide ati Sebastian wa lára ikó to soju orileede yii ni FIFA U20 Women’s World Cup to waye ninu osu kẹjọ ni Costa Rica.

Super Falcons tí o máa sábà kópa, to ti gba ife ẹ̀yẹ náà ni ìgbà mésàn án, yóò fese wonsẹ̀ pẹlú orilẹ ede Japan to ti gbade ìdíje náà ri ní ọjó Ọjọ́rú ní aago mẹ́rin aabọ̀ ti Japan iyen aago mejọ aabọ ti orílè-èdè yìí.

Àwọn ikó méjèèjì pàdé ní ìdíje Olympic ni ọdún 2004, ti ikọ̀ Nadeshiko ti Japan gbewúro sí ikọ̀ ti Falcons ti orílè-èdè Nàìjíríà lójú pẹ̀lú ayò kan sódo ni papa isere Karaiskakis ni ilu Piraeus ni ọjọ kerinla osu kẹjọ ọdún 2004. Wọn tún lu ikọ̀ Naijiria ni àlubolẹ̀ ní ìdíje oloresore ni igba meji pelu ayo meji sí odo ni ọdún
2013.

Ìdíje yií wá léyìn nkàn bí oṣù kan tí Super Falcons rin irin-ajo fún ìdíje oloresore meji pelu  USWNT ti orile-ede Amerika ti wọ́n gbá ní Kansas City ati Washington DC.

Tèmíitọ́pẹ́ Òbísèsan

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button