Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ololufẹ Olùdijé Ààrẹ Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC NÍ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ṣé Iwọde Àtìlẹ́yìn Fún

0 349

Àìmọye àwọn alatilẹyìn fún olùdijé ipò Ààrẹ Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) Asíwájú Bola Ahmed Tinubu, ṣé ìpolongo ìbó káàkiri ìgboro ìlú Ìbàdàn, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, fún àwọn olùdijé Ààrẹ Tinubu/Shettima níbí ìdìbò Gbogboògbò tó n bọ́.

Àwọn alatilẹyin náà, tí wọ́n pejọ sí Secretariat tí ẹgbẹ́ náà ní Oke-Ado ní kùtùkùtù aago mẹjọ òwúrọ̀, ní ọjọ́ Ìṣẹgun, iwọde náà fẹrẹ pa ọ̀pọlọpọ àwọn òpópó-ònà ìlú náà. Ìwọlé náà ni wọn ṣé dé Mọlete, Bẹẹrẹ, Agodi-Gate, Mọkọla, Dugbẹ pàdà sí Òkè Ado, tí wọn sì gbé pátákó tó ní oríṣìíríṣìí àkọlé tó ń fí ìfẹ wọn hàn sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó tẹlẹ rí náà.

Níbí iwọde náà tó bẹrẹ ní nnkan bí aago mọkanla àárọ̀, tí ọpọlọpọ àwọn olóṣèlú àti awọn olùdijé tí wọn n díje fún ipò oríṣiríṣi ní ìpínlẹ̀ náà labẹ àsìá APC. Olùdijé fún ipò Gómìnà ẹgbẹ ní ìpínlẹ̀ náà, Teslim Folarin tí sọ pé ẹgbẹ APC yóò sá gbogbo ipá rẹ láti gbà Ìpínlẹ̀ náà pàdà lọ́wọ́ Gómìnà Seyi Makinde tí ẹgbẹ òṣèlú People’s Democratic Party (PDP) tó sí n pé àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ náà láti dibo fún Tinubu gẹgẹ bí Ààrẹ ní ọdún 2023.

Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ náà, Isaac Omodewu, dúpẹ lọ́wọ́ àwọn alatilẹyìn ẹgbẹ náà, o sí rọ àwọn aráàlú pé kí wọn máṣe ojo kánkan tàbí bẹrù ẹgbẹ òṣèlú tó ń ṣé jọba ní ìpínlẹ̀ náà. O ní APC tí múra láti gbà ìjọba lọ́wọ́ ẹgbẹ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ náà.

Lekan orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button