Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò gbé àwọn àbá ètò ìsúná ọdún 2023 wá ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ keje, oṣù kẹwàá ọdún 2022 sí ìpàdé ìpejọ àpapọ̀ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè.
Ààrẹ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Ahmad Lawan sọ èyí di mímọ̀ ní ìpàdé tó wáyé ní Ọjọ́ Ìṣẹgun, nígbàtí o ká lẹta ti Ààrẹ fí ránṣẹ́.
Sẹnetọ Lawan sọ pé “ìpàdé náà yóò wáyé ní gbọ̀ngán tí Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣojú Ṣofin nitori iṣẹ àtúnṣe ránpẹ́ to ń lọ lọwọ ní ilẹ̀-ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àpapọ.”
O ní ètò tí wá nílẹ́ níbí ipagọ náà láti fi ààyè gbà gbogbo àwọn aṣòfin, Ààrẹ àti àwọn aṣojú rẹ̀.
Lekan orenuga
Leave a Reply