Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdìbò 2023, Ààrẹ Buhari Ń Wàásù Ìpolongo Tó Dà Lórí Ọ̀nà Àbáyọ́

0 272

Ààrẹ Muhammadu Buhari tí ṣé itẹwọgbà ipilẹsẹ tí Ìgbìmọ̀ Àlàáfíà tí Orílẹ̀-èdè yìí ṣé bí wọ́n fí ọwọ́ gbogbo awọn olóṣèlú Olùdijé ipò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà bí ìpolongo ìbó kò ṣé gbọdọ da lori inúnibíni, ẹgàn arà ẹní àti ikọlù.

Nínú fanran kàn tó fí hàn bí àwọn olùdijé Ààrẹ ṣé tọwọ́bọ̀wé bí ètò ìdìbò yóò ṣe lọ ní irọwọ tí orílẹ-èdè yóò sì wá ní àlàáfíà ni ọdún 2023, tó wáyé nípasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Àlàáfíà tí Orílẹ̀-èdè, ní Ọjọ́bọ̀ ní Ìlú Abùjá. Ààrẹ ṣé ìkìlọ bí àwọn ìròyìn ofege to jìnà sí otitọ ṣé n kọdi ìdàgbàsókè ìjọba tiwa-n-tiwa ní orílẹ̀-èdè yìí.
Òní, ìròyìn ofege náà ló tí gbokun lọ dé ibanilorukọ jẹ, àbuku àti ẹgàn. Tí èyí sì tí ń ṣé adínkú ìwà ọlaju, ọmọluwabi níbí ọrọ sísọ àti àríyànjiyàn ní gbangba láàrín àwọn olóṣèlú.

Nígbàtí o tún ṣé ìpinnu rẹ̀ pé ìdìbó tí àlàáfíà àti itẹwọgbà ati ti awọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò nifesi ní òun yóò ṣé ni ọdún 2023, Ààrẹ Buhari sọ pé òun ní ìgbàgbọ́ nínú ètò tí Ìgbìmọ̀ Àlàfíà, tí Olùdarí rẹ̀ jẹ́ olórí àti Alàkóso orílẹ̀-èdè yí tẹlẹ rí, Gen. Abdulsalami Abubukar, tí n ṣé ní àwọn ọdún melo sẹyìn ní ìbámu pẹlú àlàáfíà orílẹ-èdè yíì.

“Ìdìbò tí 2023 jẹ́ iṣẹ láti sìn Nàìjíríà, lati dáàbòbo Nàìjíríà àti láti ṣé àtìlẹ́yìn iṣọkan àti ìlọsíwájú rẹ.”

Nitorinà, mò pé gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú, àwọn olóṣèlú, àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò, Ìgbìmọ̀ eleto ìdìbò, àti gbogbo àwọn olukopa nínú ìbó láti ríi dájú pé Nàìjíríà lóun àkọkọ tó jẹ́ wá lógún.

“Mo tún rawọ ẹbẹ sí àwọn olùdijé, pàápàá jùlọ àwọn aṣojú ìkéde wọ́n àti àwọn olùdámọ̀ràn ìròyìn láti yago fún àwọn òun wọnyí.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button